SlideShare a Scribd company logo
1 of 27
Download to read offline
ashirurasheed8@gmail.com Page 1
Ewì Aládùn
Ashiru Rasheed Adékọ́lá
ashirurasheed8@gmail.com Page 2
MO DÚPẸ́
Ẹní bá ronú jinlẹ̀ yẹ kó dúpẹ́
Nítorí oore gbankọ gbankọ Olúwa
Èmí dúpẹ́ lọ́dọ̀ Ọba-Òkè
Tó tún jẹ́ kí n wà láàyè
Mo dúpẹ́ tó o dá mi lábarapá 5
N ò fiyọ àwọn àkàndá rárá
Mo fi ń gbéṣẹ́ Olúwa ga ni
Orí lorí tí mo ní
Nǹkan kan ò bá mi lórí
Orí tí mo ní ní mo fí ń róṣẹ́ Olúwa 10
Ẹsẹ̀ lẹsẹ̀ tí mo fí ń tẹ̀nà
Mo lerìn láì múgi dáni
Mo le yan fanda lórí ilẹ̀ Ọba-Òkè
Tì gbéraga kọ́
Mo fí ń dúpẹ̀ F’Ólúwa ni 15
Kì í ṣe gbogbo ẹlẹ́sẹ̀ ló ń rìnnà
Àìmọye ẹni tó ní tó ṣe pé wíwọ́ ló ń wọ́
Mo tún dúpẹ́ ọwọ́ tí mo ní
Ọwọ́ ni mo fí ń jẹun
Mo le tún fi mu nǹkan 20
Mo tún le fi ṣàtòrì fọ́mọ aláìgbọràn
Kì í ṣe gbogbo ẹní lọ́wọ́ ní ń ṣiṣẹ́
Ẹlòmíràn lọ́wọ́ ọ̀ún àmọ́ níṣe ló ń fàyà fà
ashirurasheed8@gmail.com Page 3
Àbí tẹni tó lọ́wọ́ tó ti kú ń kọ́
Rọmọlápá-rọmọlẹ́sẹ̀ ló s’ẹlòmíràn dèrò ọ̀dẹ̀dẹ̀ 25
Ah! Mo dúpẹ́ Olúwa
Ẹnu mi dápé mo fí ń yin Olúwa
Mò ń fẹnu ṣàdúrà s’Ọ́ba-Òkè
Àìmọye Ẹlẹ́nú tí kì í wíjọ́
Àìmọye elétè tí kì í sọ̀rọ̀ 30
Kì í ṣe gbogbo ẹlẹ́nu ní fi í wí
Kì í ṣe gbogbo elétè ni fi í sọ̀rọ̀
Ahọ́n mi ò gé mo dúpẹ́
Ahọ́n ń jó lébélébé nínú ẹnu
Ahọ́n lọkọ̀ tí mo fí ń tòkèlè kiri àjà 35
Ẹlòmíràn láhọ́n ṣùgbọ́n tó ti lọ́
N ò yọ̀niyàn ọpẹ́ lásán ni mò ń dú
Mélòó ni mo fẹ́ kà nínú oore Olúwa?
Mo léyín tó pé
Eyín ń ṣíṣẹ́ fún mi 40
Mó le fi gé nǹkan tópọ̀ nínú òkèlè
Mo le fi géran gẹ́ja pẹ̀lú
Mo le fi jẹ ìpékeré tó le koko
Kóróńgbó kì í bà mí lẹ́rù nílé Ẹlẹ́bẹdí
Mo le fi ge mo le fi fà mo le fi mu 45
Mo dúpẹ́ Olúwa
Kì í ṣe gbogbo eyín táa rí ló ń ṣiṣẹ́
ashirurasheed8@gmail.com Page 4
Òmíràn ò le bá pọ̀nmọ́ jà débi ẹran tó yi
Imú nimú tí mo ní
B’óúnjẹ ń jóná mo le gbọ́ 50
Bọ́bẹ̀ ti bàjẹ́ mo le mọ̀
Àìmọye imú tó parẹ́ mójú
Àìmọye kánbó tí kò wúlò
Àmọ́ imú ọ̀ún níkà kò gbóòórùn aṣebi
Mo dúpẹ́ Olúwa 55
Àìsí etí ní í sorí di pángolo
Àìsí ètè ní í méyín d’ìṣáná
Mo létí méjì
Tó dúró sasara
Tí mo fí ń gbọ́rọ̀ 60
Bénìyàn ń sọ̀rọ̀ mo gbọ́
Mo gbọ́ bí wọn ń laago
Etí mi kò di gbogbo ọ̀rọ̀ ló wọbẹ̀
Àìmọye etí tí kò gbẹ́jọ́
Àìmọyé tí kò gbọ́lù 65
Kétí tó bi kọ́ la wí kó máa gbọ́ ni
Mo dúpẹ́ Olúwa
Tí O dá mi pé
Tí n ò wà láàbọ̀.
ashirurasheed8@gmail.com Page 5
Ọ̀rọ̀ tó ta kókó
1. Àtòrì _______ẹgba
2. Kú________ tí kò ṣiṣẹ́
3. Abarapá ____ẹni tí gbogbo ẹ̀yà ara rẹ̀ pé tó sì ń ṣiṣẹ́ dáadáa.
4. Àkàndá_____ Ẹni tó ní ìpèníjà ẹ̀yà ara
5. Yọ̀_________ṣakọ
6. Kóróńgbó____Ìpápánu tó dà bí i róbó àmọ́ tí ara rẹ̀ rí ṣákaṣàka
7. Ilé-Ẹbẹdí___ Ìsẹ́yìn.
8. Ìpékeré____ọ̀gẹ̀dẹ̀ tí kò pọ́n tán tí a dín kéékèèké
9. Káńbó___imú
Ìbéèrè
1. Ẹ̀yà ara mélòó ni akéwì dárúkọ?
2. Dárúkọ àpẹẹrẹ ìfidípò mẹ́ta nínú ewì yìí.
3. Dárúkọ ẹranko kan tó máa ń fi àyà fà.
4. Dárúkọ méjì nínú ìwúlò etí àti ahọ́n.
5. Dárúkọ ohun èlò ilé-ìdáná kan tí akéwì dárúkọ.
6. Irúfẹ́ ọnà èdè wo ló wà ní ìlà 38?
7. Kí ni a máa ń pe ẹni tí ó létí ṣùgbọ́n tí kò gbọ́ nǹkan kan?
ashirurasheed8@gmail.com Page 6
KÒ LỌ TÍTÍ
Ebí le pa ni fógún ọdún bó yá
Ìyá le jẹnìyan fọ́gbọ̀n oṣù ní kòtó
Bí a bá sì wà láyé
Tóorun kò tí ì gba tọwọ́ wa
Bí a bá sì wà lókè-eèpẹ̀ 5
T’áyé sì ń rè wá lọ́wọ́
Tí a bá sì wà lókè-ilẹ̀
Tí kòtò kò tíì yá rárá
A le dirú, a le digba
A le dikòkò baba ìsasùn 10
Nígbà tá à bá kánjú
Tá ò tasẹ̀ àgẹ̀rẹ̀
Tá a dúró dàsìkò Olúwa
Kò sóhun tá ò le dà
Ẹni tí ń jeegun tẹ́lẹ̀tẹ́lẹ̀ rí 15
Ó le jẹ pọnpọlọ ẹran
Ènìyàn tí kò lẹ́wù lọ́rùn
Ó le máa fàrán ṣọlá
Ó le máa fi ṣányán ṣoge
Kó dẹni tí ń fòfì yílẹ̀ 20
Kó máa fàdìrẹ nuwọ́ epo
Bí a bá sì wà ní kòtó
A le dení, a le dèjì
ashirurasheed8@gmail.com Page 7
A le dogún, a le dọgbọ̀n pẹ̀lú
Ènìyàn tí kò nílé lórí 25
Ó le tibẹ̀ donílé ńlá
Ẹni tí kò kààsẹ̀ rí
Ó le máa kọ́lé kiri bí ẹyẹ
Ènìyàn tí ń fẹsẹ̀ rìn tẹ́lẹ̀
Ó le gbé mọ́tò bọ̀gìnnì sọ́nà 30
Kó máa dọ́lá nínú ẹṣin gidi
Bẹ́mìí bá sì wà
A le dábírà lókè èrùpẹ̀.
Ọ̀rọ̀ tó ta kókó
1. Kòtó ______ ilé ayé
2. Rè ________ tọ́jú
3. Kòtò_______ Sàréè/ọ̀run
4. Pọnpọlọ______itan
5. Ààsẹ̀ _________ilé
6. Dábírà ________ṣe rere/dáadáa
Ìbéèrè
1. Kí ni kò lọ títí?
2. Oríṣi aṣọ mélòó ni akéwì dárúkọ?
3. Kọ àwọn òǹkà tí akéwì sọ ní Èdè Gẹ̀ẹ́sì.
4. Dárúkọ ohun méjì tó le mú ènìyàn ríre láyé.
5. Irúfẹ́ ọnà èdè wo ló wà ní ìlà 28?
6. Ọnà èdè wo ló hànde ní ìlà (17)
ashirurasheed8@gmail.com Page 8
MO LỌ́GÀÁ KAN
Oríṣiríṣi ọ̀gá là á ní láyé
Ọ̀pọ̀ ẹni gíga ló pọ̀ lókè èrùpẹ̀
Kò sẹ́ni tí kò lọ́gàá
Yálà nínú ìmọ̀ tàbí lẹ́nu iṣẹ́
Yálà níléèwé tàbí nílé ìjọba 5
Onírúnrú ọ̀gá ló pọ̀ lókèèpẹ̀
Burúkú ń bẹ nínú akọ́ni
Wèré pọ̀ nínú ẹni à ń wò lókè
Àmọ́ tèmí yàtọ̀
Ọ̀gá tí mo ní yà gédéńgbé 10
Ọ̀gá mi kà nìyàn kún púpọ̀
Bẹ́ẹ̀ kì í kóyán ènìyàn kéré
Kìí fojú dìnìyàn rárá
Gbogbo ọmọ ló kó mọ́ra
Kì í ṣàbòsí ẹni ó gbéṣẹ́ fún 15
Kòdàbí àwọn ọ̀gà tí wọ́n ń pe ra wọn lọ́gàá
Àwọn irú lójú, ìrù lẹ́yìn
Ọ̀gá mi lawọ́ ó bùáyà
Bẹ́ẹ̀ kì í sí níbi ègbè rárá
Ó tún ní kiní kan tó jọjú 20
Kì í bínú àlùsì sọ́mọ-ọ̀dọ̀
Sùúrù ní í fi í bá gbogbo ọmọ ṣe
Adúró ti ni lọ́jọ́ ogún le ni
ashirurasheed8@gmail.com Page 9
Ọ̀yàyà lọ̀gá fi í bá ni lò
Àpọ́nlé ní í fún gbogbo wa 25
Kòdà bí ọ̀gá alábùkù
Tí í fọmọ-iṣẹ́ tayín oúnjẹ
Kòdà bí ọ̀gá alábùkù
Tí í ta ọmọ-iṣẹ́ rẹ̀ ní gbàǹjo
Ọ̀gá mi dára níwà púpọ̀ 30
ọmọlúwàbí lọ̀gá tí mo ní
Eniire ni mo ní lókè àkàsọ̀
Ènìyàn àtàtà lọ̀gá tí mo ní
Ọ̀gá lọ̀gá mi
Kì í ṣàwọn ọ̀gà lásánlàsàn. 35
Ọ̀rọ̀ tó ta kókó
1. Ọ̀gà_____ ẹranko kan ni tí ó máa ń yí àwọ̀ padà bó ṣe wù ú.
2. Òkè àkàsọ̀____ipò ọ̀gá
Ìbéèrè
1. Ibi mélòó ni èbìyàn ti le ní ọ̀gá?
2. Dárúkọ ohun mẹ́ta tó mú ọ̀gá akéwì yàtọ̀ sí àwọn ọ̀gá mìíràn.
3. Dárúkọ méjì lára àwọn ìwà burúkú tó wà lára àwọn.
4. Ọnà èdè wo lówà ní ìlà (16)
ashirurasheed8@gmail.com Page 10
ONÍṢẸ́ ỌBA
Kò sẹ́ni tó ń ṣèké láyé
Ọlọ́gbọ́n-ẹ̀wẹ̀ kò pọ̀ ní dúníyàn
Bí oníṣẹ́-ọba ilẹ̀ yí
Bí oníṣẹ́ ọba ilẹ̀ ẹ wa
Aríṣẹ́máṣe lọ̀pọ̀ akọ̀wé 5
Aríṣẹ́ronú lọ̀pọ̀ ọ wọn
Iṣẹ́ kì í wù wọ́n à fàwàdà
Iṣẹ́ kì í wù wọ́n àfi ẹjọ́ wẹ́wẹ́
Ọ̀rọ̀-ẹbí ni wọ́n ọ́n gbé wá síbi iṣẹ́
Ọ̀rọ̀-òṣèlú ni wọ́n ọ́n sọ nílé iṣẹ́ ìjọba 10
Àsìkò iṣẹ́ ni wọ́n rojọ́ ẹlẹ́jọ́
Àsìkò iṣẹ́ ni wọ́n ṣàròyé òṣì
Fáìlì a kún ‘wájú ẹlòmíràn gègèrè
Kò ní yẹ̀ ẹ́ wò tọ́jọ́ ó fi lọ
Bó bá wá ku dẹ̀dẹ̀ tílé ń tó ó lọ 15
Ó le fọwọ́ ta méjì nínú ọgọ́rùn-ún
Ó le ṣèkan péré nínú àádọ́ta
Ìbàjẹ́ pọ̀ lọ́wọ́ oníṣẹ́ ìjọba
Aburú wọn lé góńgó
Ìbàjẹ́ wọn lé kenkà 20
Àìtètè débi iṣẹ́ ti mọ́ wọn lára
Aago kì í lù tí wọ́n fi í kúrò lọ́fììsì
Òmíràn ti sọ iléeṣẹ́ d’Agbeni
ashirurasheed8@gmail.com Page 11
Dùgbẹ̀ lọ́fíìsì ẹlòmíràn dà
Bódìjà ń yájú nilé-iṣẹ́ ìjọba 25
Ọ̀pọ̀ ẹ̀ka ló ti di Bọ́láìgè
Níbi kátàkárà níbi iṣẹ́ ìjọba
Wọ̀n ò ṣíṣẹ́ owó tí wọ́n gbà wọ́n fún
Wọn ò ṣíṣẹ́ ọba tó ń fún wọn lóúnjẹ
Fífọwọ́hẹṣẹ ti mó wọn lára 30
Ẹ jẹ́ n wí kiníkan n tó gbàgbé
Ẹ jẹ́ ń sọ kó tó kúrò níyè
Panṣágà lọ̀pọ̀ agbèfọ́ba ń ṣe
Ọ̀gá ń bọ́mọ abẹ́ rẹ̀ ṣàgbèrè
Bí wọ́n ṣe ń bára wọn ṣe ṣìná 35
Wọ́n tún ń tawọ́ sọ́mọ-ọlọ́mọ
Èyí tó ṣèrúùlú jẹ́ẹ́jẹ́
Wọn a sọ sisí dajere kó tó lọ
Wọn a s’oge dapẹ̀rẹ̀ Àjàṣẹ̀
Yàtọ̀ sí ṣìná yàtọ̀ ságbèrè 40
Rìbá pọ̀ nílé ìjọba
Wọn kì í dá ni lóhùn àfi ká san rìbá
Wọn kì í já ni kúnra àfi ká sánwó tí í pa ni
Bíbuwọ́lu fáìlì owó ló bá dé
Bẹ́ẹ̀ kọ́bọ̀ kò d’ásùnwọ̀n ìjọba 45
Tàbí kíkan kó débẹ̀ nínú ẹgbẹ̀rún
Ìwé-mogbowó kò sí fọ́pọ̀ nǹkan
ashirurasheed8@gmail.com Page 12
Ìyẹn nílé-iṣẹ́ ìjọba
Bí ẹlòmíràn san ẹgbẹ̀rún àpò
Ìwé ọgọ́rùn-ún kan ni wọ́n fún wọn 50
Kí n tó gbàgbé ẹ jẹ́ n wí
Ẹ jẹ́ n sọ díẹ̀ lọ́rọ̀ n tó dákẹ́
Ká le mọ́ gbòò bí ẹní wẹ̀ nínú òkun
Káyé le dúró kunkun fún gbogbo wa
Ká le kúrò nínú òkùnkùn àwọn òpìjẹ̀ 55
Àwọn òpìjẹ̀ tí wọ́n ń pè lóṣìṣẹ́
Ibi àkànṣe-iṣẹ́ ni wọ́n ti dáràn tó pọ̀
Kọngílá dáràn lọ́wọ́ oníṣẹ́ ọba
Ọ̀tọ̀ lowó iṣẹ́ tíjọba sán
Owó kékeré ló tẹ kọngílá lọ́wọ́ 60
Nígbà tówó ti kò ‘jàmbá lọ́nà
Kó tó dọ́dọ̀ oníṣẹ́ gan an
Iṣẹ́ a wá di yọ̀bọ́kẹ́
Dandawì ni kọngílá ń ṣe
Páńpẹ́-ikú ni gbogbo ọ̀ná dà 65
Ọ̀pọ̀ ọ̀nà ló ti di pósí alákeji
Lẹ́yìn oṣù mẹ́fà tó parí
Ọ̀pọ̀ ẹ̀mí ló ti ṣòfò lọ́nà
Mélòó la fẹ́ kà léyín adípèlé
Tinú ọrún tìta ọ̀jọ 70
Ọ̀pọ̀ òkú ló ń gbowó ìfẹ̀yìntì
ashirurasheed8@gmail.com Page 13
Ìyẹn nílé iṣẹ́ ìjọba
Ẹlòmíràn ń gbowó ènìyàn mẹ́fà
Nílé-iṣẹ́ ìjọ̀ba náà ni
Ọjọ́-orí díndíkù pọ̀ níbẹ̀ 75
Ìbàjẹ́ kún bẹ̀ láìṣègbè.
Ọ̀rọ̀ tó ta kókó
1. Adípèlé____ eyín tó gbéra wọn pọ̀n nínú ẹnu.
2. Ọlọ́gbọ́-ẹ̀wẹ́___Ènìyàn búburú
3. Agbeni ______ọjà kan ní Ìbàdàn tí wọ́n ń ta àtẹ níbẹ̀.
4. Dùgbẹ̀_____ ọjà kan ní Ìbàdàn tí a le ra oríṣiríṣi níbẹ̀
5. Bódìjà_____ ọjà kan ní Ìbàdàn tí wọ́n ti ń ta oúnjẹ.
6. Bọ́láìgè_____ ọjà kan ní Ìbàdàn tí wọ́n ń ta oríṣi aṣọ níbẹ̀ àti bàtà. Òun náà ló tún ń jẹ́
Gbági tuntun.
7. ṣerú-ìlú_____sin ìjọba lẹ́yìn àṣeyege níléèwé gíga yálà Fásitì tàbí Polí.
8. Rìbá _______owó ẹ̀yìn
9. Òpìjẹ̀_____ Ẹni tó ń pa oko fẹ́ṣin
10. Kọngílá____ Ẹni tí a gbe àkànṣe iṣẹ́ fún
11. Kátàkárà___ òwò ṣíṣe
Ìbéèrè
1. Dárúkọ márùn-ún nínú ìwà burúkú àwọn òṣìṣẹ́ ìjọba.
2. Dárúkọ irinṣẹ́ àgbẹ̀ tí akẹ́wì dárúkọ.
3. Kọ àwọn ìlà tí akéwì ti lo ìfọ̀rọ̀dárà nínú ewì jáde.
ashirurasheed8@gmail.com Page 14
Ọ̀GÁ NI TÍSÀ
Orin
Á á kọ́mọ rẹ̀ roko o
Á á kọ́mọ rẹ̀ roko
Ẹní ni ti tísà báwo
Á á kọ́mọ rẹ̀ roko 5
Ẹni ń bóúnjẹ mọ́jú
Ebi ló yẹrú wọn lọ́jọ́kọ́jọ́
Ènìyàn tí kò mọyì òkèlè
Ẹ jẹ́ kébi sọkọ fún wọn díẹ̀
Ẹni tí kò mọyì àpọ́nlé 10
Bó kàbùkù kìí ṣèèwọ̀
Bí wọ́n bá tẹ́ kò jẹ́ nǹkan kan
Bénìyàn ò mọyì ẹ̀wù
Ẹ jẹ́ kó rìnhòhò fúngbà díẹ̀
Ènìyàn tí kò mọyì bàtà 15
Tó bá ń fẹsẹ̀ rìn kì í ṣèèwọ̀
Ẹni tí kó lójútì rárá
Ẹ̀tẹ́ ló yẹ wọ́n gedengbe
Ẹni tó ń fepó ṣòfò
Bó bá jòfún kòsí nǹkan kan 20
Kó le mọlá tó ń bẹ lára epo
Ẹni a fún lẹ́ran tí kò dúpẹ́
Ẹ jẹ́ kó jàsán fúngba díẹ̀
ashirurasheed8@gmail.com Page 15
Kó le mọyì ẹran lórí oúnjẹ
Ẹni tí kò mọyì ọ̀sà 25
Àtẹ́ ló yẹ wọ́n lọ́jọ́kọ́jọ́
Kó le mọ̀ pé ọba lọ̀sà nínú oúnjẹ
Ènìyàn tó ń kóyán tísà kéré
Àìmọ̀kan ló yẹ kó mù wọ́n dáru
Kí wọ́n le mọ̀ pé ọ̀gá làgbà 30
Olùkọ́ ni bàbá lọ́jọ́kọ́jọ́
Ohunkóhun a fẹ́ jẹ́ láyé
Iṣẹ́ tísà lópọ̀ níbẹ̀
Ohunkóhun a fẹ́ dà lókèèpẹ̀
Ọwọ́ olùkọ́ dúró wámúwámú 35
Olùkọ́ ni sábàbí Ọlá
Tísà ni atọ́kùn ọlà
Olùkọ́ lepo òun iyọ̀
Olùkọ́ ni sábàbí ìmọ̀
Kí o dí lọ́yà tàbí adájọ́ 40
Kí o di dókítà alábẹ́rẹ́ pẹ̀lú
Tàbí onímọ̀-ẹ̀rọ ló wù ọ́ lọ́kàn
Kódà bí o fẹ́ di kọ́lékọ́lé
Iṣẹ́ tísà náà ni
Bíṣègùn òyìnbó ló wù ọ́ nígbẹ̀yìn 45
Ọwọ́ olùkọ́ ò kúrò nínú ọ̀rọ̀
Ayàwòrán-ilé lo fẹ́ dà ní tìẹ
ashirurasheed8@gmail.com Page 16
Yára dìrọ̀mọ́ tísà níléèwé
Kí o le rómi ọgbọ́n bùmu
Kí o le rómi ìmọ̀ bù sansẹ̀ 50
Olùkọ́ ló kọ́ lọ́yà
Tísà ló k’ádájọ́ ilé-ẹjọ́
Olùkọ́ ló fún nọ́ọ̀sì nímọ̀ ìwòsàn
Olùkọ́ nìpìlẹ̀
Àwọn gan an lorísun. 55
Ẹ̀yin akẹ́kọ̀ọ́
Ẹ tẹ́tí ẹ gbọ́
Ẹ yéé kóyán tísà kéré
Ẹ yéé fi tísà ṣe yẹ̀yẹ́
Yéé fojúdi olùkọ́ 60
A kì í gapá s’ólùkọ́
A kì í fojú pa olùkọ́ rẹ́
Bá a rí wọn lóde ká kí wọn
Ká kí wọn bí a kò wọ́n nírònà
Ẹni àpọ́nlé ni wọ́n 65
Àbùkù ò yẹ tísà rárá
Ẹ jẹ́ á kẹ́ wọn lójú-lẹ́nu
Iṣẹ́tísà ko já wàsá
Iṣẹ́ olùkọ́ kì í ṣàwàdà
Iṣẹ́ tó le niṣẹ́ akọ́ni 70
K’Ọ́ba-Òkè ṣàánú tísà
ashirurasheed8@gmail.com Page 17
Kí wọn lọ́lálówó láyé
Kí wọ́n níyì tó pọ̀ rẹgẹdẹ
Ọ̀gá ni tísà
Kì í sọ̀rọ̀ àwàdà. 75
Ọ̀rọ̀ tó ta kókó
1. Òfún______oúnjẹ tí kò lépo
2. Àsán______ oúnjẹ tí kò lẹ́ran
3. Àtẹ́________oúnjẹ tí kò níyọ̀
4. Orísun_____ ìpìlẹ̀/ ibi tí nǹkan ti wá
Ìbéèrè
1. Dárúkọ méjì nínú ìwúlò olùkọ́.
2. Dárúkọ mẹ́ta nínú àwọn akọ́ṣẹ́mọṣẹ́ tí akéwì dárúkọ
3. Irúfẹ́ ọnà èdè wò ló wà ní ìlà 8 àti 13.
4. Dárúkọ méjì nínú aburú tó le ṣe ẹni tí kò pọ́n olùkọ́ lé.
5. Dárúkọ mẹ́ta nínú ìwà tí akẹ́kọ̀ọ́ yẹ kó hù sí olùkọ́.
6. Àdúrà mélòó ni akéwì ṣe fún olùkọ́.
7. Dárúkọ ọ̀kan nínú àṣà Yorùbá tó súyọ nínú ewì.
8. Sọ àpẹẹrẹ ìfohunpènìyàn kan tó wà nínú ewì yìí.
ashirurasheed8@gmail.com Page 18
ÈRÈ Ẹ̀KỌ́
Ìdá nìkó
Kò sóhun tí kò lérè láyé
Ohun gbogbo ló lẹ́san
Àmọ́ èré yàtọ̀
Ẹsan kò jọra wọn 5
Àsìkò èrè kò papọ̀
Èrè ń bẹ́ fẹ́kọ̀ọ́
Ìmẹ́lẹ́ náà lérè tiẹ̀
Ẹ̀kọ́ lérè ńláńlá
Ẹ jẹ́ ká múra síṣẹ́ ọpọlọ 10
Ká yéé ṣeré lásìkò ẹ̀kọ́
Ká yéé yankiri lásìkò ìmọ̀
Ká kàwé lásìkò tó yẹ
Ká ṣiṣẹ́ gbogbo ní ṣíṣe
Ká yéé ṣèmẹ́lẹ́ nínú ẹ̀kọ́ 15
Ohun tó ń bẹ lẹ́yìn ẹ̀fá pọ̀
Kódà kì í sèje
Ẹ̀kọ́ máa ń fún ni lọ́gbọ́n
Ẹ̀kọ́ le fún ni níyè
Ẹ̀kọ́ le fún ni lọ́pọlọ 20
Ó le sọ ni dọlọ́rọ̀ pẹ̀lú
Ẹ̀kọ́ ní í gbé ni níyì láwùjọ
Ẹ̀kọ́ niná
ashirurasheed8@gmail.com Page 19
Ẹ̀kọ́ lọ̀nà
Bí ẹ rí dìndìnrin tó ń sọ̀rọ̀ 25
Ẹ̀kọ́ orí ẹ̀ ni kò tó
Ló fi ń jarán lásán bí ẹran
Ẹ̀kọ́ ni kò ní lórí
Lo fi ń sọ̀rọ̀ tí kò wúlò létè
Ẹ̀kọ́ ní í mú ni lajú 30
Bí ẹ rí wèrè tí kò lọ́gbọ́n lórí
Ẹ̀kọ́ ló sá fún wọn pátá
Ẹ̀kọ́ latọ́nà ìrírí
Ẹ̀kọ́ lòògùn ìmọ̀nà
Èrè ẹ̀kọ́ kọ yọyọ 35
Ẹ̀kọ́ la fí í ṣohun gbogbo
Akẹ́kọ̀ọ́ tó bá ń fẹ̀kọ́ tàfàlà
Irú wọn kì í rérè ẹ̀kọ́ rárá
Ọmọ tó bá fẹ́ gòkè àgbà
Kò gbọdọ̀ bá ìwé rẹ̀ ṣọ̀tá 40
Akẹ́kọ̀ọ́ tó bá fẹ́ jẹgbẹ́lọ
Kò gbọdọ̀ yàn ‘wé rẹ̀ lódì
Èrè ẹ̀kọ́ pọ̀
Ẹ jẹ́ ká múra síṣẹ́ ọpọlọ.
Ìbéèrè
1. Dárúkọ mẹ́ta nínú èrè-ẹ̀kọ́
2. Dárúkọ ọnà èdè tó wà ní ìlà 27
ashirurasheed8@gmail.com Page 20
ÌWỌ, AKẸ́KỌ̀Ọ́
Iṣẹ́ lòògùn ìṣẹ́
Òògùn òṣì tí mo mọ̀ iṣẹ́ ni
Ẹní bá ṣiṣẹ́ níí jàre ìṣẹ́
Iṣẹ́ làgúnmu ìpọ́njú
Iṣẹ́ lòṣùpá ń ṣe lọ́run 5
Òòrùn ń ṣiṣẹ́ tó pọ̀ lókè
Ìràwọ̀ ń ṣiṣẹ́ tí ò kéré
Iṣẹ́ lòògùn ìṣẹ́
Iṣẹ́ ló yẹ ká jí ṣe
B’Ékò ń tàn ọ́ 10
T’Íbàdàn ń ṣòjóró
Àtẹ́lẹwọ́ ẹni kì í tan ni
Ọ̀lẹ ṣíṣe kò wúlò
Ìmẹ́lẹ́ a máa ṣe ni
Ìwọ, akẹ́kọ̀ọ́ 15
Ìwọ, alákadá
Múra ṣíṣẹ́ ọpọlọ
Iṣẹ́ ni o mú lọ́rẹ̀ẹ́
Ìwé ni o yàn láàyò
Akadá ni o fẹ́ láya lọ́kọ 20
Ìgbà kò lọ bí òréré
Ayé kò lọ bí ọ̀pán ìbọn
Àsìkò iṣẹ́ ká ṣiṣẹ́
ashirurasheed8@gmail.com Page 21
Àsìkò ìgbádùn ń bọ̀
Ká le tẹ́ pẹpẹ eré gbogbo 25
Ẹ jẹ́ ká búra lásìkò tó wúlò
Ìwọ, Akẹ́kọ̀ọ́
Kàwé níléèwé
Kí o le mọ wéè bó dọ̀la
Iṣẹ́ lòògùn ìṣẹ́ 30
Jára mọ́ṣẹ́ ọpọlọ
Kí o le rọ́wọ́mú
Múra símọ̀ ìwé
Kí o le rọ́nà tọ̀
Ìwé kíkà lodù 35
Ki o le máa yan fanda
Akẹ́kọ̀ọ́ tó kọ̀wé sílẹ̀
Àpò ìyà òun òṣì lò sokọ́
Ẹni ń fakadá pamìídìn
Òṣì ni wọ́n ń kọ lẹ́tà sí 40
Ẹni ń fẹ̀kọ́ ṣe yẹ̀yẹ́
Ó le ṣẹrú ẹgbẹ́ rẹ̀ lọ́la
Iṣẹ́ lòògùn ìṣẹ́
Múra ṣíṣẹ́, akẹ́kọ̀ọ́
Má wolé tí o ti wá 45
Kí o le rẹ́kọ̀ọ́ kọ́
Má wo tìyá tó pọ̀n ọ́ sẹ́yìn
ashirurasheed8@gmail.com Page 22
Kí o le tayọ ọgbà nínú ìmọ̀
Bàbá ti ṣe tiẹ̀ lánàá
Ìyá ti ṣe tiẹ̀ níjẹta 50
Ìwọ lo lòní
Ṣapá tìẹ náà
Iṣẹ́ ni baba ń ṣe
Ìyànjú ni baba ń gbà
Tó fi ń sanwó iléèwé 55
Múra ṣíṣẹ́ gidi
Kí o le rọ́mọ tọ́ bó dọ̀la
Kí o le rí búrùjí lògbà
Ẹ̀kọ́ ṣe kókó
Ẹ̀kọ́ lòògùn ẹ̀kọ̀ 60
Ayé a máa k’ẹni tí kò lẹ́kọ̀ọ́
Ènìyàn ẹ̀kọ̀ ní í fẹ̀kọ́ ṣẹ̀rínrín
Irú u wọn kò ṣe é farawé
Torí ẹni tó bá fẹ́ sún láyé
Irú u wọn kò gbọdọ̀ sùn 65
Má sùn, akẹ́kọ̀ọ́
Kí o le ba à sún síwájú
Ẹni ẹ̀kọ́ sá fún kì í tàn
Ẹni tí kò nítàn kì í pẹ́ tán
Yára járamọ́ṣẹ́ ọpọlọ 70
Kí o le nímọ̀ tó wàyàmì.
ashirurasheed8@gmail.com Page 23
Ọ̀rọ̀ tó ta kókó
1. Búrùjú_____ọlá
2. ṣapá______gbìyànjú
3. Ẹ̀kọ̀_______Ìkórira
Ìbéèrè
1. Dárúkọ mẹ́ta nínú ẹ̀dá Ọlọ́run tí akéwì dárúkọ tí kì í ṣe ènìyàn.
2. Dárúkọ ọ̀rọ̀ àjùmọ̀rìn méjì.
3. Sọ àpẹẹrẹ ìfidípò méjì.
4. Sọ àpẹẹrẹ ìfọ̀rọ̀dárà kan
ashirurasheed8@gmail.com Page 24
AYÉ YÌÍ !
Ilé ayé le
Dúníyàn kì í sọ̀gẹ̀dẹ̀
Ayé kì í ṣe ìkókóró
Ayé le koko bí ojú ẹja
Ènìyàn inú rẹ̀ yọ̀kànràn bí àpáàrà 5
Gbogbo ọmọ ló ranjú koko
Ọ̀pọ̀ ènìyàn ló ń hùwà òpìjẹ̀
Bámúbámú ni gbogbo ọmọ ń ṣe
Àánú ti kúrò lókè eèpẹ̀
Òtítọ́ ti dágbére fáyé 10
Irọ́ lásán ló gbayé kan
Ẹ̀tàn lásán lókù ní dúníyàn
Ọ̀rẹ́ ń dalẹ̀ ọ̀rẹ́ rẹ̀ ní kòtó
Abínibí ò rántí kòtò nínú ọ̀rọ̀
Ọ̀dàlẹ̀ lọ̀pọ̀ ìyàwó dà 15
Ọkọ ń ṣe kínlá fún yeye ọmọ
Ọmọdé ń ṣèkà
Àgbà ń ṣèké
Rírí niṣẹ́ olórí rírí
Olórí ya páńgolo ní tiwọn 20
Ọ̀pọ̀ ọ̀gá iléeṣẹ́ ni kò wúlò
Ọmọ-iṣẹ́ ni wọ́n ń gbá láta
Ṣìná lọ̀pọ̀ ènìyàn fi ń ṣadùn
ashirurasheed8@gmail.com Page 25
Akẹ́kọ̀ọ́ ò kàwé mọ́
Eégún ni wọ́n ń le kiri 25
Ọ̀pọ̀ olùkọ́ ló ń ṣe màkàrúrù
Ìmẹ́lẹ́ ni wọ́n ń ṣe níbi iṣẹ́
Ẹgbẹ̀ra wọn ni ò kójú òsùnwọ̀n
Ìjàmbá oníṣòwò ò kéré
Wọn a gbá ni lójú nídìí òwò 30
Àfi k’Ólúwa gbà wá
Ká le gúnlẹ̀ ayọ̀ nígbẹ̀yìn.
Ọ̀rọ̀ tó ta kókó
1. Dúníyàn ______ilé ayé
2. Àpáàrà_______ohun tó le koko
3. Kínlá_______ìwà burúkú/Ìfìyàjẹni
4. Rírí _______dọ̀tí
5. Eégún____màgòmágó ìdánwò
Ìbéèrè
1. Dárúkọ márùn-ún nínú àwọn ìwà ìbàjẹ́ tí akéwì dárúkọ.
2. Lo ọ̀rọ̀ míràn fún ‘’Ìjàmbá’’ gẹ́gẹ́ bó ṣe wà ní ìlà (29).
ashirurasheed8@gmail.com Page 26
ÌMỌ̀WỌ̀N ARA ẸNI
Ìmọ̀wọ̀n-ara-ẹni là á fi kómọ bí kò sówó
Ẹ jẹ́ ká ṣe bí a ti mọ
Ẹni tí kò mọ̀wọ̀n ara rẹ̀ láyé
Ìyẹn gan an lọ̀gá alábùkù
Ọmọ tí a bí tá a fewúrẹ́ kó
Oríibú kọ́ ni rárá
Èyí tó wáyé tá a so màlúù mọ́lẹ̀
Oríire rẹ̀ kọ́ ló tó bẹ́ẹ̀
Ìmọ̀wọ̀n-ara-ẹni ló yẹ ká ṣe
Ìmọ̀wọ̀n-ara-ẹni lọgbọ́n ẹni
Àìmọra-ẹni lọ̀gá àbùkú
Àfarawé latọ́kùn ẹ̀tẹ̀
Ọ̀rẹ́ mi só mo fẹ́ só
Àfàìmọ̀ ká mọ́ ṣègbọ̀nsẹ̀ sílẹ̀
Àfàìmọ̀ ni ká má ṣegá sára
Ààyò mí tọ̀ mo gbọ́dọ̀ tọ̀
Oko ẹ̀tẹ̀ la fẹ́ kọrí sí
Ìmọ̀wọ̀n-ara-ẹni lòògùn ìbàlẹ̀ ọkàn
Ẹní fì ìwàwara mórógùn ọkà
Ní í lu kòkò
Irú u wọn ní í lu apẹ
Ìwọnba aṣọ ló yẹ kẹ́wù kó jẹ́
A kì í dáṣọ bí a ṣe tó
ashirurasheed8@gmail.com Page 27
Ṣe bí o ti mọ ló yẹ ká ṣe
Kádàrá kò papọ̀
Ti Táyé yàtọ̀ sí ti Kẹ́hìndé
Ìdòwú yàtọ̀ gédéńgbé
T’Àlàbá kò jọ t’Ìdòha
Ẹ jẹ ká ṣe bí a ti mọ.

More Related Content

Viewers also liked

FINAL Paper Research (2)
FINAL Paper Research (2)FINAL Paper Research (2)
FINAL Paper Research (2)Nadine Massaad
 
ตัวแปร ชนิดข้อมูล ตัวดำเนินการ นิพจน์ และค่าคงที่
ตัวแปร ชนิดข้อมูล ตัวดำเนินการ นิพจน์ และค่าคงที่ตัวแปร ชนิดข้อมูล ตัวดำเนินการ นิพจน์ และค่าคงที่
ตัวแปร ชนิดข้อมูล ตัวดำเนินการ นิพจน์ และค่าคงที่ปณพล ดาดวง
 
Horizon 2020 2016_2017 call map for ZHAW ICBT collaboration opportunities
Horizon 2020 2016_2017 call map for ZHAW ICBT collaboration opportunitiesHorizon 2020 2016_2017 call map for ZHAW ICBT collaboration opportunities
Horizon 2020 2016_2017 call map for ZHAW ICBT collaboration opportunitiesAgnes Zoller
 
BFS GRAPH ALGORITHM
BFS GRAPH ALGORITHMBFS GRAPH ALGORITHM
BFS GRAPH ALGORITHMVishap ASar
 

Viewers also liked (6)

CIBERBULLYING
CIBERBULLYINGCIBERBULLYING
CIBERBULLYING
 
FINAL Paper Research (2)
FINAL Paper Research (2)FINAL Paper Research (2)
FINAL Paper Research (2)
 
28948ip
28948ip28948ip
28948ip
 
ตัวแปร ชนิดข้อมูล ตัวดำเนินการ นิพจน์ และค่าคงที่
ตัวแปร ชนิดข้อมูล ตัวดำเนินการ นิพจน์ และค่าคงที่ตัวแปร ชนิดข้อมูล ตัวดำเนินการ นิพจน์ และค่าคงที่
ตัวแปร ชนิดข้อมูล ตัวดำเนินการ นิพจน์ และค่าคงที่
 
Horizon 2020 2016_2017 call map for ZHAW ICBT collaboration opportunities
Horizon 2020 2016_2017 call map for ZHAW ICBT collaboration opportunitiesHorizon 2020 2016_2017 call map for ZHAW ICBT collaboration opportunities
Horizon 2020 2016_2017 call map for ZHAW ICBT collaboration opportunities
 
BFS GRAPH ALGORITHM
BFS GRAPH ALGORITHMBFS GRAPH ALGORITHM
BFS GRAPH ALGORITHM
 

Ewì aládùn

  • 1. ashirurasheed8@gmail.com Page 1 Ewì Aládùn Ashiru Rasheed Adékọ́lá
  • 2. ashirurasheed8@gmail.com Page 2 MO DÚPẸ́ Ẹní bá ronú jinlẹ̀ yẹ kó dúpẹ́ Nítorí oore gbankọ gbankọ Olúwa Èmí dúpẹ́ lọ́dọ̀ Ọba-Òkè Tó tún jẹ́ kí n wà láàyè Mo dúpẹ́ tó o dá mi lábarapá 5 N ò fiyọ àwọn àkàndá rárá Mo fi ń gbéṣẹ́ Olúwa ga ni Orí lorí tí mo ní Nǹkan kan ò bá mi lórí Orí tí mo ní ní mo fí ń róṣẹ́ Olúwa 10 Ẹsẹ̀ lẹsẹ̀ tí mo fí ń tẹ̀nà Mo lerìn láì múgi dáni Mo le yan fanda lórí ilẹ̀ Ọba-Òkè Tì gbéraga kọ́ Mo fí ń dúpẹ̀ F’Ólúwa ni 15 Kì í ṣe gbogbo ẹlẹ́sẹ̀ ló ń rìnnà Àìmọye ẹni tó ní tó ṣe pé wíwọ́ ló ń wọ́ Mo tún dúpẹ́ ọwọ́ tí mo ní Ọwọ́ ni mo fí ń jẹun Mo le tún fi mu nǹkan 20 Mo tún le fi ṣàtòrì fọ́mọ aláìgbọràn Kì í ṣe gbogbo ẹní lọ́wọ́ ní ń ṣiṣẹ́ Ẹlòmíràn lọ́wọ́ ọ̀ún àmọ́ níṣe ló ń fàyà fà
  • 3. ashirurasheed8@gmail.com Page 3 Àbí tẹni tó lọ́wọ́ tó ti kú ń kọ́ Rọmọlápá-rọmọlẹ́sẹ̀ ló s’ẹlòmíràn dèrò ọ̀dẹ̀dẹ̀ 25 Ah! Mo dúpẹ́ Olúwa Ẹnu mi dápé mo fí ń yin Olúwa Mò ń fẹnu ṣàdúrà s’Ọ́ba-Òkè Àìmọye Ẹlẹ́nú tí kì í wíjọ́ Àìmọye elétè tí kì í sọ̀rọ̀ 30 Kì í ṣe gbogbo ẹlẹ́nu ní fi í wí Kì í ṣe gbogbo elétè ni fi í sọ̀rọ̀ Ahọ́n mi ò gé mo dúpẹ́ Ahọ́n ń jó lébélébé nínú ẹnu Ahọ́n lọkọ̀ tí mo fí ń tòkèlè kiri àjà 35 Ẹlòmíràn láhọ́n ṣùgbọ́n tó ti lọ́ N ò yọ̀niyàn ọpẹ́ lásán ni mò ń dú Mélòó ni mo fẹ́ kà nínú oore Olúwa? Mo léyín tó pé Eyín ń ṣíṣẹ́ fún mi 40 Mó le fi gé nǹkan tópọ̀ nínú òkèlè Mo le fi géran gẹ́ja pẹ̀lú Mo le fi jẹ ìpékeré tó le koko Kóróńgbó kì í bà mí lẹ́rù nílé Ẹlẹ́bẹdí Mo le fi ge mo le fi fà mo le fi mu 45 Mo dúpẹ́ Olúwa Kì í ṣe gbogbo eyín táa rí ló ń ṣiṣẹ́
  • 4. ashirurasheed8@gmail.com Page 4 Òmíràn ò le bá pọ̀nmọ́ jà débi ẹran tó yi Imú nimú tí mo ní B’óúnjẹ ń jóná mo le gbọ́ 50 Bọ́bẹ̀ ti bàjẹ́ mo le mọ̀ Àìmọye imú tó parẹ́ mójú Àìmọye kánbó tí kò wúlò Àmọ́ imú ọ̀ún níkà kò gbóòórùn aṣebi Mo dúpẹ́ Olúwa 55 Àìsí etí ní í sorí di pángolo Àìsí ètè ní í méyín d’ìṣáná Mo létí méjì Tó dúró sasara Tí mo fí ń gbọ́rọ̀ 60 Bénìyàn ń sọ̀rọ̀ mo gbọ́ Mo gbọ́ bí wọn ń laago Etí mi kò di gbogbo ọ̀rọ̀ ló wọbẹ̀ Àìmọye etí tí kò gbẹ́jọ́ Àìmọyé tí kò gbọ́lù 65 Kétí tó bi kọ́ la wí kó máa gbọ́ ni Mo dúpẹ́ Olúwa Tí O dá mi pé Tí n ò wà láàbọ̀.
  • 5. ashirurasheed8@gmail.com Page 5 Ọ̀rọ̀ tó ta kókó 1. Àtòrì _______ẹgba 2. Kú________ tí kò ṣiṣẹ́ 3. Abarapá ____ẹni tí gbogbo ẹ̀yà ara rẹ̀ pé tó sì ń ṣiṣẹ́ dáadáa. 4. Àkàndá_____ Ẹni tó ní ìpèníjà ẹ̀yà ara 5. Yọ̀_________ṣakọ 6. Kóróńgbó____Ìpápánu tó dà bí i róbó àmọ́ tí ara rẹ̀ rí ṣákaṣàka 7. Ilé-Ẹbẹdí___ Ìsẹ́yìn. 8. Ìpékeré____ọ̀gẹ̀dẹ̀ tí kò pọ́n tán tí a dín kéékèèké 9. Káńbó___imú Ìbéèrè 1. Ẹ̀yà ara mélòó ni akéwì dárúkọ? 2. Dárúkọ àpẹẹrẹ ìfidípò mẹ́ta nínú ewì yìí. 3. Dárúkọ ẹranko kan tó máa ń fi àyà fà. 4. Dárúkọ méjì nínú ìwúlò etí àti ahọ́n. 5. Dárúkọ ohun èlò ilé-ìdáná kan tí akéwì dárúkọ. 6. Irúfẹ́ ọnà èdè wo ló wà ní ìlà 38? 7. Kí ni a máa ń pe ẹni tí ó létí ṣùgbọ́n tí kò gbọ́ nǹkan kan?
  • 6. ashirurasheed8@gmail.com Page 6 KÒ LỌ TÍTÍ Ebí le pa ni fógún ọdún bó yá Ìyá le jẹnìyan fọ́gbọ̀n oṣù ní kòtó Bí a bá sì wà láyé Tóorun kò tí ì gba tọwọ́ wa Bí a bá sì wà lókè-eèpẹ̀ 5 T’áyé sì ń rè wá lọ́wọ́ Tí a bá sì wà lókè-ilẹ̀ Tí kòtò kò tíì yá rárá A le dirú, a le digba A le dikòkò baba ìsasùn 10 Nígbà tá à bá kánjú Tá ò tasẹ̀ àgẹ̀rẹ̀ Tá a dúró dàsìkò Olúwa Kò sóhun tá ò le dà Ẹni tí ń jeegun tẹ́lẹ̀tẹ́lẹ̀ rí 15 Ó le jẹ pọnpọlọ ẹran Ènìyàn tí kò lẹ́wù lọ́rùn Ó le máa fàrán ṣọlá Ó le máa fi ṣányán ṣoge Kó dẹni tí ń fòfì yílẹ̀ 20 Kó máa fàdìrẹ nuwọ́ epo Bí a bá sì wà ní kòtó A le dení, a le dèjì
  • 7. ashirurasheed8@gmail.com Page 7 A le dogún, a le dọgbọ̀n pẹ̀lú Ènìyàn tí kò nílé lórí 25 Ó le tibẹ̀ donílé ńlá Ẹni tí kò kààsẹ̀ rí Ó le máa kọ́lé kiri bí ẹyẹ Ènìyàn tí ń fẹsẹ̀ rìn tẹ́lẹ̀ Ó le gbé mọ́tò bọ̀gìnnì sọ́nà 30 Kó máa dọ́lá nínú ẹṣin gidi Bẹ́mìí bá sì wà A le dábírà lókè èrùpẹ̀. Ọ̀rọ̀ tó ta kókó 1. Kòtó ______ ilé ayé 2. Rè ________ tọ́jú 3. Kòtò_______ Sàréè/ọ̀run 4. Pọnpọlọ______itan 5. Ààsẹ̀ _________ilé 6. Dábírà ________ṣe rere/dáadáa Ìbéèrè 1. Kí ni kò lọ títí? 2. Oríṣi aṣọ mélòó ni akéwì dárúkọ? 3. Kọ àwọn òǹkà tí akéwì sọ ní Èdè Gẹ̀ẹ́sì. 4. Dárúkọ ohun méjì tó le mú ènìyàn ríre láyé. 5. Irúfẹ́ ọnà èdè wo ló wà ní ìlà 28? 6. Ọnà èdè wo ló hànde ní ìlà (17)
  • 8. ashirurasheed8@gmail.com Page 8 MO LỌ́GÀÁ KAN Oríṣiríṣi ọ̀gá là á ní láyé Ọ̀pọ̀ ẹni gíga ló pọ̀ lókè èrùpẹ̀ Kò sẹ́ni tí kò lọ́gàá Yálà nínú ìmọ̀ tàbí lẹ́nu iṣẹ́ Yálà níléèwé tàbí nílé ìjọba 5 Onírúnrú ọ̀gá ló pọ̀ lókèèpẹ̀ Burúkú ń bẹ nínú akọ́ni Wèré pọ̀ nínú ẹni à ń wò lókè Àmọ́ tèmí yàtọ̀ Ọ̀gá tí mo ní yà gédéńgbé 10 Ọ̀gá mi kà nìyàn kún púpọ̀ Bẹ́ẹ̀ kì í kóyán ènìyàn kéré Kìí fojú dìnìyàn rárá Gbogbo ọmọ ló kó mọ́ra Kì í ṣàbòsí ẹni ó gbéṣẹ́ fún 15 Kòdàbí àwọn ọ̀gà tí wọ́n ń pe ra wọn lọ́gàá Àwọn irú lójú, ìrù lẹ́yìn Ọ̀gá mi lawọ́ ó bùáyà Bẹ́ẹ̀ kì í sí níbi ègbè rárá Ó tún ní kiní kan tó jọjú 20 Kì í bínú àlùsì sọ́mọ-ọ̀dọ̀ Sùúrù ní í fi í bá gbogbo ọmọ ṣe Adúró ti ni lọ́jọ́ ogún le ni
  • 9. ashirurasheed8@gmail.com Page 9 Ọ̀yàyà lọ̀gá fi í bá ni lò Àpọ́nlé ní í fún gbogbo wa 25 Kòdà bí ọ̀gá alábùkù Tí í fọmọ-iṣẹ́ tayín oúnjẹ Kòdà bí ọ̀gá alábùkù Tí í ta ọmọ-iṣẹ́ rẹ̀ ní gbàǹjo Ọ̀gá mi dára níwà púpọ̀ 30 ọmọlúwàbí lọ̀gá tí mo ní Eniire ni mo ní lókè àkàsọ̀ Ènìyàn àtàtà lọ̀gá tí mo ní Ọ̀gá lọ̀gá mi Kì í ṣàwọn ọ̀gà lásánlàsàn. 35 Ọ̀rọ̀ tó ta kókó 1. Ọ̀gà_____ ẹranko kan ni tí ó máa ń yí àwọ̀ padà bó ṣe wù ú. 2. Òkè àkàsọ̀____ipò ọ̀gá Ìbéèrè 1. Ibi mélòó ni èbìyàn ti le ní ọ̀gá? 2. Dárúkọ ohun mẹ́ta tó mú ọ̀gá akéwì yàtọ̀ sí àwọn ọ̀gá mìíràn. 3. Dárúkọ méjì lára àwọn ìwà burúkú tó wà lára àwọn. 4. Ọnà èdè wo lówà ní ìlà (16)
  • 10. ashirurasheed8@gmail.com Page 10 ONÍṢẸ́ ỌBA Kò sẹ́ni tó ń ṣèké láyé Ọlọ́gbọ́n-ẹ̀wẹ̀ kò pọ̀ ní dúníyàn Bí oníṣẹ́-ọba ilẹ̀ yí Bí oníṣẹ́ ọba ilẹ̀ ẹ wa Aríṣẹ́máṣe lọ̀pọ̀ akọ̀wé 5 Aríṣẹ́ronú lọ̀pọ̀ ọ wọn Iṣẹ́ kì í wù wọ́n à fàwàdà Iṣẹ́ kì í wù wọ́n àfi ẹjọ́ wẹ́wẹ́ Ọ̀rọ̀-ẹbí ni wọ́n ọ́n gbé wá síbi iṣẹ́ Ọ̀rọ̀-òṣèlú ni wọ́n ọ́n sọ nílé iṣẹ́ ìjọba 10 Àsìkò iṣẹ́ ni wọ́n rojọ́ ẹlẹ́jọ́ Àsìkò iṣẹ́ ni wọ́n ṣàròyé òṣì Fáìlì a kún ‘wájú ẹlòmíràn gègèrè Kò ní yẹ̀ ẹ́ wò tọ́jọ́ ó fi lọ Bó bá wá ku dẹ̀dẹ̀ tílé ń tó ó lọ 15 Ó le fọwọ́ ta méjì nínú ọgọ́rùn-ún Ó le ṣèkan péré nínú àádọ́ta Ìbàjẹ́ pọ̀ lọ́wọ́ oníṣẹ́ ìjọba Aburú wọn lé góńgó Ìbàjẹ́ wọn lé kenkà 20 Àìtètè débi iṣẹ́ ti mọ́ wọn lára Aago kì í lù tí wọ́n fi í kúrò lọ́fììsì Òmíràn ti sọ iléeṣẹ́ d’Agbeni
  • 11. ashirurasheed8@gmail.com Page 11 Dùgbẹ̀ lọ́fíìsì ẹlòmíràn dà Bódìjà ń yájú nilé-iṣẹ́ ìjọba 25 Ọ̀pọ̀ ẹ̀ka ló ti di Bọ́láìgè Níbi kátàkárà níbi iṣẹ́ ìjọba Wọ̀n ò ṣíṣẹ́ owó tí wọ́n gbà wọ́n fún Wọn ò ṣíṣẹ́ ọba tó ń fún wọn lóúnjẹ Fífọwọ́hẹṣẹ ti mó wọn lára 30 Ẹ jẹ́ n wí kiníkan n tó gbàgbé Ẹ jẹ́ ń sọ kó tó kúrò níyè Panṣágà lọ̀pọ̀ agbèfọ́ba ń ṣe Ọ̀gá ń bọ́mọ abẹ́ rẹ̀ ṣàgbèrè Bí wọ́n ṣe ń bára wọn ṣe ṣìná 35 Wọ́n tún ń tawọ́ sọ́mọ-ọlọ́mọ Èyí tó ṣèrúùlú jẹ́ẹ́jẹ́ Wọn a sọ sisí dajere kó tó lọ Wọn a s’oge dapẹ̀rẹ̀ Àjàṣẹ̀ Yàtọ̀ sí ṣìná yàtọ̀ ságbèrè 40 Rìbá pọ̀ nílé ìjọba Wọn kì í dá ni lóhùn àfi ká san rìbá Wọn kì í já ni kúnra àfi ká sánwó tí í pa ni Bíbuwọ́lu fáìlì owó ló bá dé Bẹ́ẹ̀ kọ́bọ̀ kò d’ásùnwọ̀n ìjọba 45 Tàbí kíkan kó débẹ̀ nínú ẹgbẹ̀rún Ìwé-mogbowó kò sí fọ́pọ̀ nǹkan
  • 12. ashirurasheed8@gmail.com Page 12 Ìyẹn nílé-iṣẹ́ ìjọba Bí ẹlòmíràn san ẹgbẹ̀rún àpò Ìwé ọgọ́rùn-ún kan ni wọ́n fún wọn 50 Kí n tó gbàgbé ẹ jẹ́ n wí Ẹ jẹ́ n sọ díẹ̀ lọ́rọ̀ n tó dákẹ́ Ká le mọ́ gbòò bí ẹní wẹ̀ nínú òkun Káyé le dúró kunkun fún gbogbo wa Ká le kúrò nínú òkùnkùn àwọn òpìjẹ̀ 55 Àwọn òpìjẹ̀ tí wọ́n ń pè lóṣìṣẹ́ Ibi àkànṣe-iṣẹ́ ni wọ́n ti dáràn tó pọ̀ Kọngílá dáràn lọ́wọ́ oníṣẹ́ ọba Ọ̀tọ̀ lowó iṣẹ́ tíjọba sán Owó kékeré ló tẹ kọngílá lọ́wọ́ 60 Nígbà tówó ti kò ‘jàmbá lọ́nà Kó tó dọ́dọ̀ oníṣẹ́ gan an Iṣẹ́ a wá di yọ̀bọ́kẹ́ Dandawì ni kọngílá ń ṣe Páńpẹ́-ikú ni gbogbo ọ̀ná dà 65 Ọ̀pọ̀ ọ̀nà ló ti di pósí alákeji Lẹ́yìn oṣù mẹ́fà tó parí Ọ̀pọ̀ ẹ̀mí ló ti ṣòfò lọ́nà Mélòó la fẹ́ kà léyín adípèlé Tinú ọrún tìta ọ̀jọ 70 Ọ̀pọ̀ òkú ló ń gbowó ìfẹ̀yìntì
  • 13. ashirurasheed8@gmail.com Page 13 Ìyẹn nílé iṣẹ́ ìjọba Ẹlòmíràn ń gbowó ènìyàn mẹ́fà Nílé-iṣẹ́ ìjọ̀ba náà ni Ọjọ́-orí díndíkù pọ̀ níbẹ̀ 75 Ìbàjẹ́ kún bẹ̀ láìṣègbè. Ọ̀rọ̀ tó ta kókó 1. Adípèlé____ eyín tó gbéra wọn pọ̀n nínú ẹnu. 2. Ọlọ́gbọ́-ẹ̀wẹ́___Ènìyàn búburú 3. Agbeni ______ọjà kan ní Ìbàdàn tí wọ́n ń ta àtẹ níbẹ̀. 4. Dùgbẹ̀_____ ọjà kan ní Ìbàdàn tí a le ra oríṣiríṣi níbẹ̀ 5. Bódìjà_____ ọjà kan ní Ìbàdàn tí wọ́n ti ń ta oúnjẹ. 6. Bọ́láìgè_____ ọjà kan ní Ìbàdàn tí wọ́n ń ta oríṣi aṣọ níbẹ̀ àti bàtà. Òun náà ló tún ń jẹ́ Gbági tuntun. 7. ṣerú-ìlú_____sin ìjọba lẹ́yìn àṣeyege níléèwé gíga yálà Fásitì tàbí Polí. 8. Rìbá _______owó ẹ̀yìn 9. Òpìjẹ̀_____ Ẹni tó ń pa oko fẹ́ṣin 10. Kọngílá____ Ẹni tí a gbe àkànṣe iṣẹ́ fún 11. Kátàkárà___ òwò ṣíṣe Ìbéèrè 1. Dárúkọ márùn-ún nínú ìwà burúkú àwọn òṣìṣẹ́ ìjọba. 2. Dárúkọ irinṣẹ́ àgbẹ̀ tí akẹ́wì dárúkọ. 3. Kọ àwọn ìlà tí akéwì ti lo ìfọ̀rọ̀dárà nínú ewì jáde.
  • 14. ashirurasheed8@gmail.com Page 14 Ọ̀GÁ NI TÍSÀ Orin Á á kọ́mọ rẹ̀ roko o Á á kọ́mọ rẹ̀ roko Ẹní ni ti tísà báwo Á á kọ́mọ rẹ̀ roko 5 Ẹni ń bóúnjẹ mọ́jú Ebi ló yẹrú wọn lọ́jọ́kọ́jọ́ Ènìyàn tí kò mọyì òkèlè Ẹ jẹ́ kébi sọkọ fún wọn díẹ̀ Ẹni tí kò mọyì àpọ́nlé 10 Bó kàbùkù kìí ṣèèwọ̀ Bí wọ́n bá tẹ́ kò jẹ́ nǹkan kan Bénìyàn ò mọyì ẹ̀wù Ẹ jẹ́ kó rìnhòhò fúngbà díẹ̀ Ènìyàn tí kò mọyì bàtà 15 Tó bá ń fẹsẹ̀ rìn kì í ṣèèwọ̀ Ẹni tí kó lójútì rárá Ẹ̀tẹ́ ló yẹ wọ́n gedengbe Ẹni tó ń fepó ṣòfò Bó bá jòfún kòsí nǹkan kan 20 Kó le mọlá tó ń bẹ lára epo Ẹni a fún lẹ́ran tí kò dúpẹ́ Ẹ jẹ́ kó jàsán fúngba díẹ̀
  • 15. ashirurasheed8@gmail.com Page 15 Kó le mọyì ẹran lórí oúnjẹ Ẹni tí kò mọyì ọ̀sà 25 Àtẹ́ ló yẹ wọ́n lọ́jọ́kọ́jọ́ Kó le mọ̀ pé ọba lọ̀sà nínú oúnjẹ Ènìyàn tó ń kóyán tísà kéré Àìmọ̀kan ló yẹ kó mù wọ́n dáru Kí wọ́n le mọ̀ pé ọ̀gá làgbà 30 Olùkọ́ ni bàbá lọ́jọ́kọ́jọ́ Ohunkóhun a fẹ́ jẹ́ láyé Iṣẹ́ tísà lópọ̀ níbẹ̀ Ohunkóhun a fẹ́ dà lókèèpẹ̀ Ọwọ́ olùkọ́ dúró wámúwámú 35 Olùkọ́ ni sábàbí Ọlá Tísà ni atọ́kùn ọlà Olùkọ́ lepo òun iyọ̀ Olùkọ́ ni sábàbí ìmọ̀ Kí o dí lọ́yà tàbí adájọ́ 40 Kí o di dókítà alábẹ́rẹ́ pẹ̀lú Tàbí onímọ̀-ẹ̀rọ ló wù ọ́ lọ́kàn Kódà bí o fẹ́ di kọ́lékọ́lé Iṣẹ́ tísà náà ni Bíṣègùn òyìnbó ló wù ọ́ nígbẹ̀yìn 45 Ọwọ́ olùkọ́ ò kúrò nínú ọ̀rọ̀ Ayàwòrán-ilé lo fẹ́ dà ní tìẹ
  • 16. ashirurasheed8@gmail.com Page 16 Yára dìrọ̀mọ́ tísà níléèwé Kí o le rómi ọgbọ́n bùmu Kí o le rómi ìmọ̀ bù sansẹ̀ 50 Olùkọ́ ló kọ́ lọ́yà Tísà ló k’ádájọ́ ilé-ẹjọ́ Olùkọ́ ló fún nọ́ọ̀sì nímọ̀ ìwòsàn Olùkọ́ nìpìlẹ̀ Àwọn gan an lorísun. 55 Ẹ̀yin akẹ́kọ̀ọ́ Ẹ tẹ́tí ẹ gbọ́ Ẹ yéé kóyán tísà kéré Ẹ yéé fi tísà ṣe yẹ̀yẹ́ Yéé fojúdi olùkọ́ 60 A kì í gapá s’ólùkọ́ A kì í fojú pa olùkọ́ rẹ́ Bá a rí wọn lóde ká kí wọn Ká kí wọn bí a kò wọ́n nírònà Ẹni àpọ́nlé ni wọ́n 65 Àbùkù ò yẹ tísà rárá Ẹ jẹ́ á kẹ́ wọn lójú-lẹ́nu Iṣẹ́tísà ko já wàsá Iṣẹ́ olùkọ́ kì í ṣàwàdà Iṣẹ́ tó le niṣẹ́ akọ́ni 70 K’Ọ́ba-Òkè ṣàánú tísà
  • 17. ashirurasheed8@gmail.com Page 17 Kí wọn lọ́lálówó láyé Kí wọ́n níyì tó pọ̀ rẹgẹdẹ Ọ̀gá ni tísà Kì í sọ̀rọ̀ àwàdà. 75 Ọ̀rọ̀ tó ta kókó 1. Òfún______oúnjẹ tí kò lépo 2. Àsán______ oúnjẹ tí kò lẹ́ran 3. Àtẹ́________oúnjẹ tí kò níyọ̀ 4. Orísun_____ ìpìlẹ̀/ ibi tí nǹkan ti wá Ìbéèrè 1. Dárúkọ méjì nínú ìwúlò olùkọ́. 2. Dárúkọ mẹ́ta nínú àwọn akọ́ṣẹ́mọṣẹ́ tí akéwì dárúkọ 3. Irúfẹ́ ọnà èdè wò ló wà ní ìlà 8 àti 13. 4. Dárúkọ méjì nínú aburú tó le ṣe ẹni tí kò pọ́n olùkọ́ lé. 5. Dárúkọ mẹ́ta nínú ìwà tí akẹ́kọ̀ọ́ yẹ kó hù sí olùkọ́. 6. Àdúrà mélòó ni akéwì ṣe fún olùkọ́. 7. Dárúkọ ọ̀kan nínú àṣà Yorùbá tó súyọ nínú ewì. 8. Sọ àpẹẹrẹ ìfohunpènìyàn kan tó wà nínú ewì yìí.
  • 18. ashirurasheed8@gmail.com Page 18 ÈRÈ Ẹ̀KỌ́ Ìdá nìkó Kò sóhun tí kò lérè láyé Ohun gbogbo ló lẹ́san Àmọ́ èré yàtọ̀ Ẹsan kò jọra wọn 5 Àsìkò èrè kò papọ̀ Èrè ń bẹ́ fẹ́kọ̀ọ́ Ìmẹ́lẹ́ náà lérè tiẹ̀ Ẹ̀kọ́ lérè ńláńlá Ẹ jẹ́ ká múra síṣẹ́ ọpọlọ 10 Ká yéé ṣeré lásìkò ẹ̀kọ́ Ká yéé yankiri lásìkò ìmọ̀ Ká kàwé lásìkò tó yẹ Ká ṣiṣẹ́ gbogbo ní ṣíṣe Ká yéé ṣèmẹ́lẹ́ nínú ẹ̀kọ́ 15 Ohun tó ń bẹ lẹ́yìn ẹ̀fá pọ̀ Kódà kì í sèje Ẹ̀kọ́ máa ń fún ni lọ́gbọ́n Ẹ̀kọ́ le fún ni níyè Ẹ̀kọ́ le fún ni lọ́pọlọ 20 Ó le sọ ni dọlọ́rọ̀ pẹ̀lú Ẹ̀kọ́ ní í gbé ni níyì láwùjọ Ẹ̀kọ́ niná
  • 19. ashirurasheed8@gmail.com Page 19 Ẹ̀kọ́ lọ̀nà Bí ẹ rí dìndìnrin tó ń sọ̀rọ̀ 25 Ẹ̀kọ́ orí ẹ̀ ni kò tó Ló fi ń jarán lásán bí ẹran Ẹ̀kọ́ ni kò ní lórí Lo fi ń sọ̀rọ̀ tí kò wúlò létè Ẹ̀kọ́ ní í mú ni lajú 30 Bí ẹ rí wèrè tí kò lọ́gbọ́n lórí Ẹ̀kọ́ ló sá fún wọn pátá Ẹ̀kọ́ latọ́nà ìrírí Ẹ̀kọ́ lòògùn ìmọ̀nà Èrè ẹ̀kọ́ kọ yọyọ 35 Ẹ̀kọ́ la fí í ṣohun gbogbo Akẹ́kọ̀ọ́ tó bá ń fẹ̀kọ́ tàfàlà Irú wọn kì í rérè ẹ̀kọ́ rárá Ọmọ tó bá fẹ́ gòkè àgbà Kò gbọdọ̀ bá ìwé rẹ̀ ṣọ̀tá 40 Akẹ́kọ̀ọ́ tó bá fẹ́ jẹgbẹ́lọ Kò gbọdọ̀ yàn ‘wé rẹ̀ lódì Èrè ẹ̀kọ́ pọ̀ Ẹ jẹ́ ká múra síṣẹ́ ọpọlọ. Ìbéèrè 1. Dárúkọ mẹ́ta nínú èrè-ẹ̀kọ́ 2. Dárúkọ ọnà èdè tó wà ní ìlà 27
  • 20. ashirurasheed8@gmail.com Page 20 ÌWỌ, AKẸ́KỌ̀Ọ́ Iṣẹ́ lòògùn ìṣẹ́ Òògùn òṣì tí mo mọ̀ iṣẹ́ ni Ẹní bá ṣiṣẹ́ níí jàre ìṣẹ́ Iṣẹ́ làgúnmu ìpọ́njú Iṣẹ́ lòṣùpá ń ṣe lọ́run 5 Òòrùn ń ṣiṣẹ́ tó pọ̀ lókè Ìràwọ̀ ń ṣiṣẹ́ tí ò kéré Iṣẹ́ lòògùn ìṣẹ́ Iṣẹ́ ló yẹ ká jí ṣe B’Ékò ń tàn ọ́ 10 T’Íbàdàn ń ṣòjóró Àtẹ́lẹwọ́ ẹni kì í tan ni Ọ̀lẹ ṣíṣe kò wúlò Ìmẹ́lẹ́ a máa ṣe ni Ìwọ, akẹ́kọ̀ọ́ 15 Ìwọ, alákadá Múra ṣíṣẹ́ ọpọlọ Iṣẹ́ ni o mú lọ́rẹ̀ẹ́ Ìwé ni o yàn láàyò Akadá ni o fẹ́ láya lọ́kọ 20 Ìgbà kò lọ bí òréré Ayé kò lọ bí ọ̀pán ìbọn Àsìkò iṣẹ́ ká ṣiṣẹ́
  • 21. ashirurasheed8@gmail.com Page 21 Àsìkò ìgbádùn ń bọ̀ Ká le tẹ́ pẹpẹ eré gbogbo 25 Ẹ jẹ́ ká búra lásìkò tó wúlò Ìwọ, Akẹ́kọ̀ọ́ Kàwé níléèwé Kí o le mọ wéè bó dọ̀la Iṣẹ́ lòògùn ìṣẹ́ 30 Jára mọ́ṣẹ́ ọpọlọ Kí o le rọ́wọ́mú Múra símọ̀ ìwé Kí o le rọ́nà tọ̀ Ìwé kíkà lodù 35 Ki o le máa yan fanda Akẹ́kọ̀ọ́ tó kọ̀wé sílẹ̀ Àpò ìyà òun òṣì lò sokọ́ Ẹni ń fakadá pamìídìn Òṣì ni wọ́n ń kọ lẹ́tà sí 40 Ẹni ń fẹ̀kọ́ ṣe yẹ̀yẹ́ Ó le ṣẹrú ẹgbẹ́ rẹ̀ lọ́la Iṣẹ́ lòògùn ìṣẹ́ Múra ṣíṣẹ́, akẹ́kọ̀ọ́ Má wolé tí o ti wá 45 Kí o le rẹ́kọ̀ọ́ kọ́ Má wo tìyá tó pọ̀n ọ́ sẹ́yìn
  • 22. ashirurasheed8@gmail.com Page 22 Kí o le tayọ ọgbà nínú ìmọ̀ Bàbá ti ṣe tiẹ̀ lánàá Ìyá ti ṣe tiẹ̀ níjẹta 50 Ìwọ lo lòní Ṣapá tìẹ náà Iṣẹ́ ni baba ń ṣe Ìyànjú ni baba ń gbà Tó fi ń sanwó iléèwé 55 Múra ṣíṣẹ́ gidi Kí o le rọ́mọ tọ́ bó dọ̀la Kí o le rí búrùjí lògbà Ẹ̀kọ́ ṣe kókó Ẹ̀kọ́ lòògùn ẹ̀kọ̀ 60 Ayé a máa k’ẹni tí kò lẹ́kọ̀ọ́ Ènìyàn ẹ̀kọ̀ ní í fẹ̀kọ́ ṣẹ̀rínrín Irú u wọn kò ṣe é farawé Torí ẹni tó bá fẹ́ sún láyé Irú u wọn kò gbọdọ̀ sùn 65 Má sùn, akẹ́kọ̀ọ́ Kí o le ba à sún síwájú Ẹni ẹ̀kọ́ sá fún kì í tàn Ẹni tí kò nítàn kì í pẹ́ tán Yára járamọ́ṣẹ́ ọpọlọ 70 Kí o le nímọ̀ tó wàyàmì.
  • 23. ashirurasheed8@gmail.com Page 23 Ọ̀rọ̀ tó ta kókó 1. Búrùjú_____ọlá 2. ṣapá______gbìyànjú 3. Ẹ̀kọ̀_______Ìkórira Ìbéèrè 1. Dárúkọ mẹ́ta nínú ẹ̀dá Ọlọ́run tí akéwì dárúkọ tí kì í ṣe ènìyàn. 2. Dárúkọ ọ̀rọ̀ àjùmọ̀rìn méjì. 3. Sọ àpẹẹrẹ ìfidípò méjì. 4. Sọ àpẹẹrẹ ìfọ̀rọ̀dárà kan
  • 24. ashirurasheed8@gmail.com Page 24 AYÉ YÌÍ ! Ilé ayé le Dúníyàn kì í sọ̀gẹ̀dẹ̀ Ayé kì í ṣe ìkókóró Ayé le koko bí ojú ẹja Ènìyàn inú rẹ̀ yọ̀kànràn bí àpáàrà 5 Gbogbo ọmọ ló ranjú koko Ọ̀pọ̀ ènìyàn ló ń hùwà òpìjẹ̀ Bámúbámú ni gbogbo ọmọ ń ṣe Àánú ti kúrò lókè eèpẹ̀ Òtítọ́ ti dágbére fáyé 10 Irọ́ lásán ló gbayé kan Ẹ̀tàn lásán lókù ní dúníyàn Ọ̀rẹ́ ń dalẹ̀ ọ̀rẹ́ rẹ̀ ní kòtó Abínibí ò rántí kòtò nínú ọ̀rọ̀ Ọ̀dàlẹ̀ lọ̀pọ̀ ìyàwó dà 15 Ọkọ ń ṣe kínlá fún yeye ọmọ Ọmọdé ń ṣèkà Àgbà ń ṣèké Rírí niṣẹ́ olórí rírí Olórí ya páńgolo ní tiwọn 20 Ọ̀pọ̀ ọ̀gá iléeṣẹ́ ni kò wúlò Ọmọ-iṣẹ́ ni wọ́n ń gbá láta Ṣìná lọ̀pọ̀ ènìyàn fi ń ṣadùn
  • 25. ashirurasheed8@gmail.com Page 25 Akẹ́kọ̀ọ́ ò kàwé mọ́ Eégún ni wọ́n ń le kiri 25 Ọ̀pọ̀ olùkọ́ ló ń ṣe màkàrúrù Ìmẹ́lẹ́ ni wọ́n ń ṣe níbi iṣẹ́ Ẹgbẹ̀ra wọn ni ò kójú òsùnwọ̀n Ìjàmbá oníṣòwò ò kéré Wọn a gbá ni lójú nídìí òwò 30 Àfi k’Ólúwa gbà wá Ká le gúnlẹ̀ ayọ̀ nígbẹ̀yìn. Ọ̀rọ̀ tó ta kókó 1. Dúníyàn ______ilé ayé 2. Àpáàrà_______ohun tó le koko 3. Kínlá_______ìwà burúkú/Ìfìyàjẹni 4. Rírí _______dọ̀tí 5. Eégún____màgòmágó ìdánwò Ìbéèrè 1. Dárúkọ márùn-ún nínú àwọn ìwà ìbàjẹ́ tí akéwì dárúkọ. 2. Lo ọ̀rọ̀ míràn fún ‘’Ìjàmbá’’ gẹ́gẹ́ bó ṣe wà ní ìlà (29).
  • 26. ashirurasheed8@gmail.com Page 26 ÌMỌ̀WỌ̀N ARA ẸNI Ìmọ̀wọ̀n-ara-ẹni là á fi kómọ bí kò sówó Ẹ jẹ́ ká ṣe bí a ti mọ Ẹni tí kò mọ̀wọ̀n ara rẹ̀ láyé Ìyẹn gan an lọ̀gá alábùkù Ọmọ tí a bí tá a fewúrẹ́ kó Oríibú kọ́ ni rárá Èyí tó wáyé tá a so màlúù mọ́lẹ̀ Oríire rẹ̀ kọ́ ló tó bẹ́ẹ̀ Ìmọ̀wọ̀n-ara-ẹni ló yẹ ká ṣe Ìmọ̀wọ̀n-ara-ẹni lọgbọ́n ẹni Àìmọra-ẹni lọ̀gá àbùkú Àfarawé latọ́kùn ẹ̀tẹ̀ Ọ̀rẹ́ mi só mo fẹ́ só Àfàìmọ̀ ká mọ́ ṣègbọ̀nsẹ̀ sílẹ̀ Àfàìmọ̀ ni ká má ṣegá sára Ààyò mí tọ̀ mo gbọ́dọ̀ tọ̀ Oko ẹ̀tẹ̀ la fẹ́ kọrí sí Ìmọ̀wọ̀n-ara-ẹni lòògùn ìbàlẹ̀ ọkàn Ẹní fì ìwàwara mórógùn ọkà Ní í lu kòkò Irú u wọn ní í lu apẹ Ìwọnba aṣọ ló yẹ kẹ́wù kó jẹ́ A kì í dáṣọ bí a ṣe tó
  • 27. ashirurasheed8@gmail.com Page 27 Ṣe bí o ti mọ ló yẹ ká ṣe Kádàrá kò papọ̀ Ti Táyé yàtọ̀ sí ti Kẹ́hìndé Ìdòwú yàtọ̀ gédéńgbé T’Àlàbá kò jọ t’Ìdòha Ẹ jẹ ká ṣe bí a ti mọ.